Smiley face

Awon omo ole ka Basketmouth mole loru oganjo

Oladeji Kehinde 
Nǹkan ò s̩e̩nu re̩ fún gbajúmó̩ aláwàdà náà, Bright Okpocha, e̩ni tí gbogbo èèyàn mò̩ sí Basketmouth, nígbà tí àwo̩n adigunjalè ló̩ jà á ní olè ní ilé rè̩ tí ó wà ní Lekki ní Ojobo (Thursday) tí ó ko̩já yìí.

Nǹkan bíi aago méjì òru ni àwo̩n ìgárá náà ya wo̩ inú ilé rè̩ tí wó̩n sì kóun àti e̩bí rè̩ mó̩ra fún nǹkan bí wákàtí méjì.

O̩pé̩ pé wo̩n ò s̩e e̩niké̩ni lés̩e nínú is̩è̩lè̩ àmó̩ ò̩pò̩lo̩pò̩ dúkíà olówóiyebíye ní wó̩n jí kó lo̩. Kí Olúwa ma s̩ó̩ wa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment