Smiley face

Funke Akindele ti keyin si amoran awon ololufee re

https://web.facebook.com/photo.php?fbid=349754315376562&set=gm.1322339607817345&type=3&theater
Pelu gbogbo amoran ti awon oloufee Funke Akindele fun osere naa lati se jeje nipa gbigbe ara re saye pelu oko re tuntun, odabi eni wi pe eyin eti Jenifa ni oro naa bo si.

Opolopo awon eniyan lo gba wi pe, ayelujara wa lara ohun to n se akoba fun igbeyawo opo awon gbajumo osere wa. Gbogbo ohun ti n sele labe orule won ni won gbe saye.

Awon Yoruba si bo, won ni ile eni lati n je ekute onidodo.

Sugbon sa, awon kan gba wi pe ohun gbogbo wa lowo kadara. Akunleyan ni adayeba, adayeba ni adayese.

Won ni ohun ti eniyan gbe sori ayelujara ko ni itunmo gidi, bikose ayanmo ti onikaluku gbe wa si duniyan.

Gege bi awon agbalagba abileko ti Olayemi Oniroyin fi oro wa lenu wo se so, awon gba wi pe, iwa loba awure fun obirin lati ri ile oko gbe. Bakan naa ni won tun tenumo pataki itelorun.

Ju gbogbo re lo, yotomi ni Funke Akindele aya Bello wa lana pelu oko re leyin tiwon pari ise oojo won. Bi won se n fi enu ko ara won lenu bee ni Sulia gbe ori le oko re laya. Sebi won ti ni ori ni yoo porun, orun ni yoo pori. Ti ife ba n dun laaarin ololufee meji, bi igba eniyan gba visa wonu paradisi ni.

Adura mi ni wi pe, ki Edumare tete ba mi da Jenifa lohun, ki oun naa fowo gbe omo aridunnu jo. Amin
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment