Smiley face

Asotele wooli: Awon ota ma doju ija ko Yemi Osinbajo lodun 2017

Apostle Johnson Suleman
Wooli agbaye, Apostle Johnson Suleman, ti so asotele lara ohun ti yoo sele lodun 2017 eleyii to ni i se pelu wi pe, laasigbo, fitinati, wahala, rugudu yoo deba igbakeji Aare ile Naijiria, Ojogbon Yemi Osinbajo.

Ohun ti wooli yii so naa ni wi pe, ni odun 2017, igba meji otooto ni won yoo gbiyanju lati yo oko Dolapo loye sugbon ti Olorun awon omoogun Isireli yoo si dide iranlowo fun un.

Ti e ko ba gbagbe, Apostle Johnson Suleman to je adari ijo Omega Fire Ministries International so asotele saaju eto idibo wi pe, Donald Trump ti ilu Amerika ati Nana Akufo-Addo ti ilu Ghana ni yoo wole gege bi Aare eleyii ti asotele mejeeji si wa si imuse.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment