Smiley face

Kemi Olunloyo ti pada sori ọrọ Seun Egbegbe

Kemi Omololu-Olunloyo
Gbajugbaja akoroyin to tun jẹ ọmọ gomina ipinle Ọyọ nigba kan ri, Kemi Olunloyọ ti bẹrẹ si ni naka aleebu si awon olopaa ile Naijiria pelu bi won se lajuulẹ bi Seun Egbegbe se rin irin-ajo lo siluu Malaysia.

Loju opo Kemi, @HNNAfrica, lori ero twitter, ko sai tun ke gbajari si awon agbofinro ilu Malaysia lati ta won lolobo wi pe, Seun Egbegbe, ẹni ti n dajo idaran lọwọ niluu Naijiria, ti wo ilu won.

Gẹgẹ bi iwadii Olayemi Oniroyin, titi di akoko yii, awon olopaa Naijiria ko ti fi esi kankan sita lori oro naa. 

Ninu oro akoroyin to ti fi igba kan gbe niluu Canada, Kemi Olunloyo, ni awon olopaa Naijiria ja awon eniyan ni tanmọọ pelu asise won nipa bi Seun Egbegbe se jade niluu Naijiria nigba ti ko ti yanju esun idaran to wo sorun bi alakọrun.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment