Smiley face

Princess Elizabeth Onanuga: Irawọ osere ti won wo ni United Kingdom

Princess Elizabeth Onanuga

Aimoye ẹyẹ lo n kọrin nigbo, sugbọn ọtọ ni tẹyẹ àwoko. Eniyan le fi ologbo se apejuwe amọtẹkun, sugbon gbogbo wa loye wi pe ọde ju ọde lọ.


Aimoye osere onitiata lo wa lotito, sugbon ẹbun, ọgbọn atinuda ati agbekale isẹ ọpọlọ to fakiki mu Princess Elizabeth Onanuga yato gedegede. Eleyii si wa lara ohun to mu okiki rẹ lekenka niluu ọba Elisabẹẹti.


Ilu ọba Biritiko ni Ọmọọbabirin Elizabeth tẹdo si, oserebirin yii yoo si ma balẹ sori eto GBEDEMUKE pelu Olayemi Oniroyin lori Radio Diaspora lọjọ kẹwaa, osu kejila odun yii (December 10, 2016) ni deede ago merin si marun-un irole, àkókò Naijiria (4pm-5pm WAT).

Ẹyin naa le darapo mọ eto naa lori www.radiodiaspora.com.ng lati gbọ wa lọjọ Satide (10-12-16) ti n bo yii ni deede ago merin akoko Naijiria.
Okan ninu awon ami-ẹyẹ ti Princess gba ninu odun yii ni yii
E le fi awon ibeere yin sọwọ si mi saaju ọjọ Satide nipa ohun ti ẹ fẹ mọ nipa Princess Elizabth Onanuga sori: +2348032394964  
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment