Smiley face

Iwadii nipa Seun Egbegbe: Se ise aye ni tabi amutorunwa? 2

Opolopo awon eniyan ni won wi pe, ise aye ni awon isele ti n sele si Seun Egbegbe nigba ti awon kan so wi pe ise ole gan-an ni ise re.


Awon aheso oro wonyii ko je ka le so ni pato boya ise aye ni looto tabi amutorunwa (talenti) ni. 

Sugbon gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, lati nnkan bi odun merin seyin si igba taa wa yii, a ko le naka si ise fiimu kankan pataki ti ile ise okunrin naa, Ebony Films and Records, gbe jade. [Eni to ba ni eri to yato ko so fun wa] 

Aridaju si wa wi pe, okunrin yii ra awon moto, lara re ni Range Rover to gbe fun Toyin Aimakhu nigba ti ife won si n gbona. 

O seese ki okunrin yii ni ise mii ti a wa ko mo, sugbon oun to pe nise re naa ni fiimu sise. Aimoye igba ni Kemi Olunloyo si ti tako o wi pe, okunrin naa kan fise fimu boju lasan ni. 

Siwaju sii, ni akoko ti isele foonu waye ninu oja Computer Village, aimoye orisii awon oloja bi merin si marun-un ni won jeri wi pe, igba akoko ko ni yii ti Seun Egbegbe yoo ma wa sinu oja naa lati ja won lole. [Awon fidio naa wa lori Youtube]

E je ki n duro nibeyen, ka tun wo idakeji re. Se ise aye ni isele to n sele si Seun Egbegbe? 

Ti e ba seranti ni nnkan bi odun meloo kan seyin, osere kan naa wa ti won lo n jale, Yetunde Akilapa. Won fura wi pe oro re ki i se oju lasan, awon agba elere dide pelu awon ebi omobirin naa lati se iranlowo fun un. A ko si gbo iroyin buruku nipa re mo.

E je ki n tun fun ni apere asemase to waye laaarin awon onise fiimu. Se e ranti Yetunde Wunmi to gbe ogun oloro (cocaine)? 

Bi o tile je wi pe agbarijo awon egbe onifiimu koro oju si asemase naa, sibesibe, awon ni won se itoju fun awon omo re ni awon akoko to fi wa lewon. 

Igba to jade, won fe yoo legbe sugbon won tun pada darijin, won faa leti, bakan naa ni won se atileyin fun un lati fi itan aye re se fiimu nipa isele to sele si.

Ohun ti mo fe fayo ni wi pe, iru isele yii ti sele saaju, yala eyi to lowo aye ninu tabi eyi to je afowofa, eleyii ti awon egbe onifiimu dide iranwon. Sugbon nipa ti oro Ogbeni Egbegbe, n se ni gbogbo won wo bi eni wi pe won ko gbo iroyin to n lo. 

Oseese ki awon naa gba wi pe jaguda paraku ni Seun Egbegbe gege bi Kemi Olunloyo se so.

Lara iwadii ti mo se, won ni pupo awon eniyan ti aye ba fi adanwo ole jija kan[aye ko ni fi adanwo kan wa, ase], won ni nnkan itiju tabi ohun ti ko wulo si won ni won ma n ji. 

Bi apere, won le bi elomii nile ola, lai si se wi pe iya n je e, eni naa le lo si aarin oja lati loji bi #1000 tabi ohun ti ko wulo bi bata tabi aago kekere kan. 

Lopo igba, awon to ba ni adanwo yii, bi won se maa n jale ki i mogbon dani. Eyi tunmo si wi pe, ko si bi won se fe jale ti owo ki i te won. 

Bi apere, eni to ba ni adanwo yii le lo si ile ore te ti yoo si ji foonu pamo sinu baagi re lai pa foonu naa.

Ohun ti mo fe fayo ni wi pe, iru awon eniyan bayii ki i lo opolopo laakaye ninu ole ija won. Awon nnkan keekeke ti ko ni tunmo si aye won ni won ma n ji.

Gbogbo alaye yii lo je idakeji Seun Egbegbe, awon nnkan nla ni Seun Egbegbe ma n ji. Bakan naa lo ma n lo orisiirisii opolo lati fi jale. 

Ohun kan pataki ti mo tun fe ke e kiyesi ni wi pe, awon ti won ba ni adanwo ole jije, won ki i wa eni kunra ki won to jale. 

Igba ti Seun Egbegbe lo jale foonu ninu oja Computer Village, oun nikan ko lo lo. O kan je wi pe oun nikan ni owo te ni. Enikan kan lo wa moto ti Seun Egbegbe gbe lo.

Bakan naa, eleyii to sele ni Gbagada, owo te enikeji re ti won jo n gbiyanju lati ja Gambari lole. 

Ninu alaye ti awon kan se fun wa, won ni oju lasan ko n Seun Egbegbe fi n jale. A ti wi pe, o seese ki ogun ti n lo ti sunko ti oun gan-an ko si fura.

Ki lo wa mu Toyin Aimakhu to fi di ololufe Seun Egbegbe? 

Mi o ti pari....






















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment