Smiley face

Kini itunmo ojulowo ife?

Ayojo awon ololufe n bo lona! Ife ti o labawon a si maa dun bi oyin. Kini ife tunmo si tabi bawo ni a se le salaye ife? Ohun to koju senikan, eyin lo ko si elomii.

Orisiirisii itunmo ni eniyan si le fun ohun ta n pe ni ife. Gege bi oye kekere ti temi, emi ri ohun ti won pe nife gege bi kika asise enikeji wa si asise lasan.

Eyi tunmo si wi pe, ti enikan ba se wa, ko ba dara ju ti ba kakun asise lasan. Niwon igba ti a ba ti kakun asise, sise idariji fun enikeji wa yoo ya kiakia.

Ko ba je omo, alabagbe, omoose tabi ololufe eni. Kika asise eniyan si asise lasan ma n je ki ibasepo, ibagbepo ati ife wa gun ko si larinrin. Kosi ba a se fe e rin ti ori ko ni mi. Kosi ba se fe gunyan ewura ti ko ni ni koko. Kosi bi sanmo yoo se funfun tibi kan ko ni dudu. Kosi bi ase fe gbe ile aye lai ku sibi kan. Kosi bi ahon at'ehin se fe gbepo ninu enu ti won ko ni kolura won.

Kini awon nnkan ti eyin ro wi pe o ma n ba ife je tabi ki awon nnkan to ma mu ife dun ti yoo si pe?

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment