Smiley face

Awon ebi ko gba ki Victor Olaiya gba ipe ori foonu leyin iku Moji omo re

Moji Olaiya, oserebirin onitiata ti o jade laye lonii,18-05-2017, ni orileede Canada leni odun mejilelogoji ti mu ibanuje okan ba awon ololufe fiimu agbelewo, eleyii ti won se alaye iku re gege bi ohun to ba won lojiji.

Wayio, Olayemi Oniroyin gbiyanju lati pe awon ebi Dr Victor Olaiya to je okan lara awon agba olorin ile Naijiria ati baba fun Moji to doloogbe.

Ohun ti a gbo ni wi pe, iroyin isele buruku naa ko se fi pamo fun baba bo tile je wi pe ko dun mo awon ninu ki baba maa gba iru iroyin ibanuje naa.

Awon ebi ati ojulumo ti wa pelu baba bayii. Bakan naa ni won ko gba ko gba ipe kankan lori foonu lasiko yii.

Adura wa ni wi pe, ki Edumare ba wa tu idile won ninu. Amin

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment