Smiley face

Odaju eda ti n fi omo sowo eru



Image result for child trafficking
Mmmmmh! Gbogbo onise dudu aye nibo lẹ fẹ ba ile aye ja. Sekaseka, ẹ ranti ẹsẹ mefa, ọjọ tẹ ẹ sun tẹ ò si ni ji saye mọ.

E sfun ọdaju ẹda ko ranti Gaa Ọṣọrun. Nitori t’ogun ba jẹ lọ, ọgbọn ko ni salai jẹbọ dandan ni. 

Awon ọmọọlọmọ ni won ko lọ sòwò ẹru lokeere. Awon ọmọ ti won o mọtun yato sosi ni won kolọ ilu ajoji sise idoti, Won gba majesin lọwọ ẹni o niwon lo sise aséwó, isẹ ibanujẹ nibi won ko ti gbe lẹbi, nibi won ko ti gbe lara, ti ko si senikan aa ke pe. Kilode?

Ẹ n fi ọgbọn alumonkoriyi gba awon ọmọ wonyii lọwọ awọn obi to bi won, pelu ọrọ asọdun wi pe, ẹ fẹ ran won lowo ni. Sugbon nigba ti won kuro labẹ iya won tan, ti won debi oju ọlọmọ ò to o, nigba ti won dọna-ò-gbeji ti ko sibi a a gba pada sile, nibi ọmọ ti gbe n lọgun baba-yeye ti ki i rẹni je ni “oo iwo da?”.  Mmmmmmh!

Nibẹ lẹ ti bẹrẹ si ni le awọn ọmọ wonyii sori igba bi buredi. E sọ ọmọ ẹda eniyan dọja ti won ta nigbanjo nitori aa la ni duniyan. Bi ẹ ko tile bẹru eniyan, ẹ si bẹru ọba adakẹja bi iji ti mbẹ lajule orun.

Jojoojumo nibadi aran fomije takoto idi seleleya nibi won ti gbe n mu nomba leyin odi. Ika ti n gbowo ori won mbe nibooji ti n feja tutu mogi. Sugbon Ọmọ n fesi ohun oju rẹ ri lajo ranse sile, awon obi ni o gbọ bẹẹ eti won o si di. Obi ọmọ mbe nile reti ọmọ ti o ni pada seri wale mo.   Igbeyiningbeyin lawon obi omo to fura wi pe, ika eniyan ti n sebi ore ti sewon nijamba ona ti jin. mmmmmm

Ero okun, ero ọsa, ẹ wa teti gbo labare ohun to sele laba ti wa.

Iya alaanu ti ma n wa saba wa lọdọọdun tun ti de pẹlẹbun repete. O ni awon ọmọ ti oun ko lọ lesin ni won fẹbun ohun ranse sile.

Inu gbogbo ara ile dun sinsin bi ẹni layin. Atagba-atọmọde ni won fo soke bi ẹni rolugbala. 

Gbogbo won dunnu wi pe, awon ọmọ awon ti n rise. Iya alaanu a tun mu lẹta arumje a fi le won lọwọ, a ni awon ọmọ won lo ko leta ohun ranse. Opolopo omo lo tun ko lo lodun eyi.

Iya alaanu ni ile ẹkọ ni won l niluu nla, ti won ba pari ni won sisẹ aje ti won pawo gidi. Eni ọmọ rẹ ti n kọse ọwọ ni ko dawoduro ko tẹle ika eniyan rinrin-ajo aremabo. Ẹni to ye kọmọ rẹ bẹrẹ ile iwe lodun ti n bọ  ni koun naa ma ba won lolu nla lọ soriire. 

A lo lari, a ki i rabọ won. Gbogbo ara ile ni i dunnu pe omo awon ko nipe kawe gboye deniyan pataki. Sugbon ise buruku ni won fi won se. Omo oloomo laa ran nise detorutoru, omo oloomo ni won ran nise iku. To ba leku ko ku sebi omo oloomo ni.

Won ti gbagbe wi pe, eni gbin ebu ika, omoomo re yoo je nibe. Won ti gbagbe wi pe, oko ta so mo ope lope o pada so moni.

Awon omo to ye ki won wa nile iwe, le n ko lọ sisẹ gbẹmigbẹmi. E fi won sise nabi, e n fi won pawo. E mu won tipatikuuku ki won ma baja ba omo eranko sun tori wi pe e fe dolola ojiji. Won on tun ma fi won gbe ogun oloro koja lenu bode, ko sara ti won ki i fomolomo da. Kosi ise buruku ti won ki i fi won se.

Bo ba wu won, won le fi won guse owo, eleyii to ba fe tu won lasari ni won ran lajule orun. Emi eniyan ko jo awon ika eniyan loju. 

Bi won ba fẹ ko awon omoọlọmọ ni won se bi onise Oluwa. Bi won ba mọmọ jina sokerere tan ni won pa won lekun jaye.

Lesebo lesoogun, boba laya o seka, Sugbon to baranti igbeyin Gaa Oshorun mi o ba bee o ko gbaye serere. Ko yee ko omoolomo rinrin ajo losigbo odaju, e yee  gba ona eburo ko ogo ojo ola ile iyi danu si koto Nitori ti ogun ba jẹ lọ, ogbon ko ni salai jẹbo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment