Smiley face

SÙÚRÙ GBÈ MÍ (Apá karùn-ún) lati owo Oluko Ede Yoruba

Mo kí ẹ̀yin ènìyàn àtàtà tí ẹ̀ ń ka ìtàn yìí pé ẹ kú ìfẹ́ o. Èyí ni ìtẹ̀síwájú ìtàn aládùn yìí, ẹ máa bá wa bọ̀:

Abájáde àyèwò fi hàn pé mo ti lóyún osù méjì. Ìyá Adébáyò kókó gbé èrín ìyàngì, ó rérìn-ín kèékèékèé kí ó tó wá fèsì lé e pé : "ó tán àbókù? kóo wá gbóyún gba yunifásítì lo lókù, nnkan ire náà wu elésìn-ín ara re. Kí n yara pe bàbá re báyìí kí ó lè mò pé o ti gbé òrò èkó re dórí "gb" dúró, o ò ní le dé "y" mọ́. Oníyẹ̀yẹ́ tó fẹ́ kàwé toyún-toyún.
Èmi fúnra mi mọ̀ pé agbaja ti pin lọ́wọ́ oníjó mi, nítorí pé oyún tí mo ní ti fàlù Àyánníyì ẹ̀kọ́ mi ya. Bàbá mi so ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí mi, wọ́n sì fẹnukò sí wí pé kí ẹni tí ó fún mi lóyún ó yọjú sílé( Ìyá Adébáyọ̀ ò bìkítà láti mọ ẹni tí ó fún mi lóyún, igbe kí n gbóyún lọ ibi tí mo ti rí i ló n ké).


Mo gbéra ó di ilé àwọn Ọlákúnlé, nígbà tí mo dé ibẹ̀ pẹ̀lú àbúrò bàbá mi kan ni mo gbọ́ pé Ọlákúnlé àti áwọn ẹbí rẹ̀ yòókù ti kó lọ sí ìlú Èkó láti máa gbé pẹ̀lú bàbá wọn bí ẹbí kan àti wí pé wọ́n ti ta ilé tí a wà níbẹ̀, nítorí náà a ò rí ìròyìn pàtó láti lè mọ ibi tí wọ́n ń gbé.

Mo wolẹ̀ sùn bí ẹni tí aágànná ta lé, mo jára pàtì bí ẹni tí yèèsì gbọ̀n lù, mo wá gbára dálẹ̀ bí ẹni ọ̀fọ́ ṣẹ̀. Kò jọ gbígbé kò jọ wíwọ́ ni Ìyá Ayọ̀ tí a jọ lọ fi mú mi délé. Ọkàn mi kò wọlé àmọ́ mi ò ríbi lọ mọ́.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ibi tí ẹ lọ tóo fi ń wò sùn bí ẹni tí ọkọ̀ já sílẹ̀? Ní ìbéèrè tí ìyá Adébáyọ̀ fi kí wa káàbọ̀. Ẹnu tèmi ò gbọ̀rọ̀, ìyá Ayọ̀ ni ó jábọ̀ ibi tí a lọ. Ìyá Adébáyọ̀ tu bí ejò, ó ní láá àfi dandan kí n wá ẹni tó loyún kàn tàbí kí n wá ibi lọ nítorí pé òun ò lè gbà kín máa gbóyún ọmọ tí ò ní bàbá gbélé.

Nígbà tí ìyá Adébáyọ̀ ti yarí kanlẹ̀ ni àwọn ara ilé àti àdúgbò tí wọ́n ti pé léwa lórí bá panupọ̀ rọ ìyá Ayọ̀ láti mú mi sọ́dọ̀. Ìyá Ayọ̀ sọ wí pé ilé tí màá gbé kọ́ ni ìsòro bí kò se àtijẹ-àtimu mi.

Mo yára dáhùn pé màá wáṣẹ́ ṣe, àti wí pé mi ò ní yọ wọ́n lẹ́nu rárá. Ìyá Ayọ̀ gbà àmọ́ ó ní màá ṣe sùúrù ọ̀sẹ̀ kan kí òun fi bá baálé òun sọ̀rọ̀.
Ní ìgbà tí ọ̀sẹ̀ kan pé, ìyá Ayọ̀ padà wá mú mi lọ sí ìlú Òṣogbo. Láàrin oṣù méjì tí mo dé ibẹ̀ ni àwọn ọ̀rẹ́ ìyá Ayọ̀ ti mọ̀ mí dáadàa látàrí bí mo ṣe jára mọ́ṣẹ́. Iṣẹ́ Aránṣọ ni ìyá Ayọ̀ ń ṣe tí mo sì máa ń kún wọn lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àmọ́ àtẹ ni èmi ń dọ́gbọ́n tà tí mo sì máa ń kiri.


Àbúrò bàbá Ayọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adébọ̀wálé ni ó bá mi sọ̀rọ̀ pé mo sì lè gba fọ́ọ̀mù ìdánwò àṣewọlé ẹ̀kọ́ gíga, ó sàlàyé bí mo ṣe lè gbà á nítorí pé akẹ́kọ̀ọ́ ni òun náà. Ọkàn mi balẹ̀ pé mo ti ní bùrọ̀dá Bòwálé (bí mo ti máa ń pèé nù un) gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn pàtàkì.


Ní alẹ́ ọjọ́ àbámẹ́tá kan, gbogbo ẹbí bàbá Ayọ̀ ni wọ́n lọ sí Ìbàdàn fún ayẹyẹ pàtàkì kan, ìtìjú ni kò jẹ́ kí èmi ó bá wọn lọ.


Òjò tí ó rọ̀ ní ọjọ́ yìí mú kí oorun mi ó tọra. Ṣàdéédé ni mo gbúròó ọwọ́ lẹ́nu ọ̀nà, àyà mí là gààrà, àmọ́ nígbà tí mo gbóhùn Adébọ̀wálé mo yára dìde sí ìlẹ̀kùn, ó bèèrè àwon ará ilé mo sì ṣàlàyé pé wọ́n ròde.


Ó pààrọ̀ aṣọ, mo sì wá oúnjẹ fún un. Nígbà tí ó jẹ̀un tán tí èmi dágbére láti lọ sùn ni ó bá he mí lápá, bí ó ti fẹ́ fàmí báyìí ni mo jáwọ́, ǹjẹ́ kí n sáré wọ yàrá mi ni ó bá kì mí lójijì, mo jà fitafita(èmi tí inú okùnrin ń bí tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ohun tí Olákúnlé se fún mi). Nígbà tí ipá mi kò fẹ́ káa, mo gbé irin kan tí mo rí ní ẹgbẹ́ ilé, mo sì jàn án mọ̀ ọ́n, ó lọgun tòò ó sì nalẹ̀, ariwo tí ó pa dẹ́rù bà mí( mo ṣe bí ó kú ni) sàdéédé ni òòyì gbé mi tí èmi náà sì nalẹ̀.

*********** **

Nígbà tí mo lajú ni mo gbọ́ pé mo ti lo ọjọ́ mẹ́rin nílé ìwòsàn àti wí pé oyún mi ti wálẹ̀. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ mo padà sílé àmọ ìlú́ Ìwó ni Adébọ̀wálé lọ lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Ìyá Ayọ̀ bá mi wí gidigidi fún ìwà ìkà tí mo wù sí Adébọ̀wálé nítorí pé ọgbẹ́ rẹ̀ pọ̀ lápọ̀jù.


ṢÉ ÌWÀ ÌKÀ NI MO WÙ SÍ ADÉBỌ̀WÁLÉ NI ÀBÍ MO FI OHUN TÍ MO RÍ GBÀ ARA MI?

ÌHÀ WO NI Ẹ̀YIN KO SÍ Ọ̀RỌ̀ OYÚN TÍ Ó WÁLẸ̀ YÌÍ?

Ìtàn yìí ń tẹ̀ síwájú.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment