Smiley face

Àwọn abiyamọ ni eléyìí wá fun

Ẹ má fi ọmọ yín obirin ti ọkùnrin kankan, yala ọrẹ tàbí ìbátan.

E máa sọ́ ọmọbìnrin yín nípa ibi tó ń jẹ̀ sí. E ma je ki ẹnikẹ́ni fọwọ́ kan ọmọbìnrin yín ní ọ̀nà àìtọ́.

Bákan náà , ẹ kọ́ ọmọbìnrin yín bí wọ́n ṣe ń paramọ́.

Lákòótán, ẹ má sọ wí pé ọmọde ni wọn, ẹ jẹ ki àwọn ọmọ yín ni òye nípa ibalopo tí wọ́n bá ti ń dàgbà àti ewu tó rọ mọ ọ.

Ẹ si rántí so fun won ohun tí wọn ni láti ṣe ni pajawiri nígbà tí ìkà ènìyàn bá fẹ́ ṣe wọn  ní jamba.

Àfikún, ẹ jẹ ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ yìn, ẹ jẹ ki wọn finu tán yín, ẹ jẹ ki wọn ní ìgbàgbọ́ nínú yín láti bá yín sọ ohunkóhun tó bá ń dùn wọn lọ́kàn.

Ìbànújẹ́ kò ní dapo mo ayọ́ wá. Ọmọ aráyé kò ní dá òkúta sínú iyọ́ wa. Àmín

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment