Smiley face

Seun Egbegbe ti ká ABD débi GBi! O loun tí gba fun kadara

Láti oṣù kejì ọdún 2017 ta wa yìí ni ilé ẹjọ́ to ga julo ni ìlú Èkó tí ni kí wón gba béèlì Seun Egbegbe, sibesibe, ko si oluranlowo to setan lati saanu fun un.

Léyìn fóònù tí ọkọ Toyin Aimakhu nigba kan lọ jí ni computer village to wa ni agbegbe Ikeja, ọkùnrin olokoowo fiimu sise náà tún gbìyànjú láti lu àwọn gambari tí wọ́n sewo dollar ni milionu merin owo naira ni agbegbe Gbagada.

Ní àkókò tí Seun Egbegbe jale eleekeji yìí, ọ̀ràn fóònù tó jí sí wa ni kootu eleyii ti ko ti parí.

Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, Seun Egbegbe ti lo to osu mẹ́wàá logba ẹ̀wọ̀n látàrí airi oniduro.

Onidajo Oluremi Oguntoyinbo to ni ki won gba béèlì rẹ losu kejì ọdún yìí kò béèrè fún àwọn oniduro lásán.

Ó ní irú àwọn ènìyàn lawujo tó lè dúró fún Seun Egbegbe àti ohun pato tí wọ́n ni láti ṣe.

Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ ko nira láti tu Seun Egbegbe silẹ.

Nje kí ni àwọn nǹkan tí ónidajo Oluremi Oguntoyinbo ń béèrè fún?

Ẹ yẹ àtẹ yìí wo fún abala kejì (2) ìròyìn yii

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment