Smiley face

"Flora my flowa" Davido tí dá gobe silẹ

Mo fẹ́ràn láti máa kàwé. Orisirisi ìwé ni mo sì ti kà nípa òdòdó àti ìwúlò rẹ layika.

Yàtọ̀ sí ẹ̀ṣọ́ ilé, fifi ojú kó òdòdó má n jẹ ki ènìyàn gbe ọkàn kúrò nínú ẹ̀dùn ọkàn, bákan náà lo ni agbara lati fún ọkàn ní ìtura.

Mo tilẹ̀ ká ìwé kan tó sọ nípa bí òdòdó ṣe dára láti fi bù ọlá fún òkú ọrùn, àti wí pé àwọn òdòdó náà a má jẹ ìtẹ́wọ́gbà gidi gan-an.

Àpilẹ̀kọ ọmọ India 🇮🇳 kan tí mo kà tilẹ tún ṣàlàyé rẹpẹtẹ bí òdòdó ṣe ṣe pàtàkì gege bí èròjà ìrúbọ sì àwọn òrìṣà wọn.

Ó lójú òdòdó tí mi ò mọ orúkọ àti oríkì rẹ nínú ìmò sayensi [ìgbéraga ti bẹ̀rẹ̀ 😂]. Àwọn orúkọ oríkì sayensi bí Transcendence Zenyatta, Soldravangaluku  oru,  Gardenia jasminoides,  Mitrephora winitii mélòó gan-an là fẹ́ ká nínú ehin Adipele?

Jù gbogbo rẹ lọ, àní àwọn òdòdó alátọwọ́dá bákan náà là ní ojúlówó to jẹ èwe gidi ti wọn gbìn, kosi sì èyíkéyìí tí wọn kò lè fi ṣe ẹ̀ṣọ́ ilé bí irú èyí tí ẹ ń wo nínú àwòrán yii.

ÌBÉÈRÈ: Orúkọ oríkì wo ni àwọn onímọ̀ sayẹnsi ń pé òdòdó tó wà ní àwòrán yìí?

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment