Smiley face

Ìrìn àjò ni ilé ayé jẹ

Àwọn kan jókòó, àwọn kan dúró. Wọn yẹ àwọn kan sí ní árà ọ̀tọ̀, nígbà tí àwọn kan kò rí àyèsí gba. Wọn fi ìwé pé àwọn kan, nígbà tí àwọn kan bẹbẹ láti ríbi dúró sí. Wọ́n ọ́n wo àwọn kan bí tẹ́lì📺 nígbà tí àwọn kan wà wòran lásán.

Àwọn kan jókòó lórí àga kuṣin sia níwájú nígbà ti àwọn kan jókòó lórí plastic chair lẹ́yìn. Eléyìí ń ṣe àpẹẹrẹ ilé ayé. Bó ṣe wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ni yìí bẹẹ ni yóò sì rí títí di òpin ayé.

Ohun tí mo fẹ́ mú jáde gan-an mi ò tí débẹ̀. Má rọyin kí ẹ gbà mí láàyè kí n sọ nípa Selif Keita, ọmọ ìlú Mali 🇲🇱.

Keita jẹ àgbà olórin niluu Mali bí ìgbà tí a bá ń sọ nípa Sunny Ade ni Nigeria bẹẹ ni Keita ṣe tóbi tó. Nínú orin rẹ lo tí ṣe àkàwé kan tí mi ò lè gbàgbé.

Ó ní ti wọn ba ko ọmọdé mẹ́wàá jọ, tí wọn wá ní kí wọn sáré ìje síwájú. Ó ní ti àwọn ọmọdé yii ba dé ilaji ọ̀nà, tí wọn wá tún pàṣẹ kí wọn sáré padà lórí ère lai dúró.

Ó ní ohun tó má ṣẹlẹ̀ ni wí pé, ẹni tó ti ń léwájú tẹ́lẹ̀ ni yóò padà kẹyin. Nígbà tí ẹnì to wá lẹ́yìn pátápátá tẹ́lẹ̀ ni ó padà jẹ nomba 1 nígbà tí wọn ba sáré padà lai dúró. Keita ni bí ilé ayé seri nígbà míì ni yẹn.

Àti àwọn ènìyàn tí wọn jókòó àti àwọn tó dúró, kosi ẹni tó ti de òpin ìrìn àjò wọn. Tí àwọn tó jókòó bá kọ láti tesiwaju, oseese kí àwọn ènìyàn má pọn lè mọ to bá dọ̀la. Bákan náà sì rèé, tí àwọn ènìyàn tí kò rí àyè jókòó bá lè múra sí igbiyanju wọn, àwọn náà le deni apọnle ti yóò jókòó lórí kuṣin sia lọ́la.

Irin àjò ní ilé ayé, ikú nìkan lópin àjò ẹ̀dá. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀dá kò bá tíì kú, kò sí ìgbà tí kò lè dá bá ẹ̀dá láyé. Kí Edumare jẹ ki ìgbà rere de ba wa.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment