Smiley face

Ọjọ́ ìbí olùkọ́ mi : Omowe Clement Odoje

Omowe Clement Odoje
Bí babaláwo bá ń sọdún Ifá
Won a mú Ifá ire kawo tí ń sọdún Orunmila.
Pasitọ kò ní ṣajọdun kí wọn má ká Sáàmù láéláé.
Báwo láti fẹ́ kí omowe láì ṣí tákàdá wò?
Èyí ló mú mi rántí Iṣola 1978, page 26 (line 33-34).
"B'ọlọ́gbọ́n bá fìwà kẹ́wà tán,
Kò le è má fi gbogbo ara wù ni".
Ìwà ọmọlúwàbí lo mú Omowe Odoje wù mí. 
Bó ṣe lọ́gbọ́n orí tó, kò fìgbéraga kún un. 
Bó ṣe nímọ̀ tó kìí ṣaṣeju. 
Igbá ilé rẹ kò ní fọ
Àwo ilé rẹ ko ni fàya. 
Bó bá lo ẹgbẹ̀rún ọdún láyé ò ni mòṣì. 
Igba ọdún, ọdún kan ni. 
Happy Birthday 🎂 

Ire ❤️ 

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment