Smiley face

Ọ̀nà àbáyọ fún àwọn tó bá ní oòrùn ara (Body Odour)

Ǹjẹ́ ẹ ṣe àkíyèsí wí pé ẹni oòrùn ara (Body Odour)? 

Ohùn tí ẹ lè ṣe ni yìí ti e ba ni òórùn ara (body odour). 

Ẹ wá ọsan wẹẹrẹ eleyii ti wọn tun pé ní ọṣàn wẹ́wẹ́ (lemon). Ẹ gee si méjì, kí ẹ sì fi fọ abiya yín tí ó bá ti ku bí iseju márùn-ún sí mẹ́wàá tí ẹ fẹ́ lọ wẹ.

Ọsan wẹ́wẹ́ tí ẹ gé yìí nìkan ni  ẹ má fi fọ abiya yín méjèèjì. 

Tí ẹ bá ti fọ ọ tán, ẹ fi silẹ bẹẹ fún bí ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá. 

Lẹ́yìn èyí, ẹ lè lọ wẹ̀ ìwẹ̀ àárọ̀ yín kí ẹ tó jáde nílé.

Tí ẹ  bá ń ṣe eléyìí nígbà gbogbo , saka ni ara yín yóò má dá lai si oòrùn ara kankan tàbí ohun tí wọn pé ní body odour. 

Tí ẹ bá ń ṣe eléyìí, ẹ kò nílò pafiimu kankan nítorí òórùn kankan kò ní jẹyọ láti ara yín mọ. 

Mo dúpẹ́ fún àkókò yín tí ẹ fi ka àlàyé yìí.
 
Olayemi Olatilewa 
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment