Awon Yoruba bo, won bi omode o batan yoo ba aroba, aroba sini baba itan.
Nje kini Yoruba n pe ni aroba?
Aroba ni ohun ti a foju ri ti o n se apeere isele to ti koja lo laimoye odun seyin. Aroba yii ni o fidi itan taa gbo mule wi pe otito ni iru isele bee sele.
Gbajugbaja onkorin takasufe Oladapo Olaitan Olaonipekun, ti gbogbo eniyan mo si Dagrin ti o je Olorun nipe ninu ijamba oko to waye ni ojo kejilelogun, osu kerin odun 2010 ti di ohun ti won ni itan ko le gbagbe lailai.
Leyin odun keta ti Dagrin ti lo, ajodun odun keta yii ni won se nipa sise oko Dagrin eleyii to ku sinu re losoo gege bi ohun iranti akoni to lo.
Dagrin ti a bi ni ojo kokanlegun osu kewa (21 October 1987)je eni ti gbogbo eniyan gba gege bi ogbontarigi onkorin takasu eleyii ti o se amulu ede Yoruba ju lo ninu orin re.
Adura wa ni wi pe ki Edua oke pa asise re mo. Sun re oo, Dagrin(CEO awon omo ita)
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment