Smiley face

ISE IROYIN, ISE ORIN 2

Olorin Loga Akoroyin

Litireso gege bi okan lara ise ona je ohun alagbara ti ki i ku boro. Sugbon iriri ati akiyesi fi ye wa wi pe ise litereso kan a maa tewon ju omiiran lo.

Aimoye apileko alaye ni awon onise oniroyin ti gbe jade, eleyii ti o je wi pe igba ti won jade naa ni awon orisii ise bee fi lo igba mo lawujo.

Sugbon pupo ninu alaye awon olorin ti won se sinu orin won si n ja rainrain nile titi di igba yii wa.

Eyi si mu wa gba wi pe ise iroyin awon olorin a maa pe laye ju ti awon oniroyin ode iwoyii lo.


Orisiirisii ona ni awon olorin le gbe ise iroyin won gba, eleyii ni i se pelu ohun to pe akiyesi won tabi ise ti awon eniyan ran won lati je fun ara ilu.

Olorin le menu ba alaye nipa oro oselu, esin, eto eko, imoran tabi ipolowo oja.

Iru awon nnkan bayii ki i kuro lawujo kiakia agaga ti iru olorin bee ba lo je eni aye n fe.

Nje a wa le gba lotito wi pe agbara ti orin ni lo so olorin di oga akoroyin? Se nnkan miiran tun mbe ninu ise iroyin leyin ka fonrere isele tabi akiyesi eni?
Ki ni mbe leyin Ofa to Joje lo?

Olayemi Oniroyin, emi ni mo wi pe ojo ti o ti da, a ko le so iyi eniyan ti o pa.

E ku ikale
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment