Igba Lailai
Awon Yoruba bo, won ni ki agbado to o daye, kinikan ni adiye n je. Ki ise iroyin sise too di gbajugbaja o ti ni awon kan ti won ti n royin faye gbo tele ri.
Iwadii si fi ye wa wi pe ise iroyin igba naa si je eleyii to lagbara ju lo.
Eni to ba so wi pe olorin loga oniroyin, a ko le pe iru eni bee lakuri lailai. Nitori wi pe ki ise oniroyin to o wa saye ni awon olorin ti royin ohun oju won ri lati ileto kan si ekeji.
Ni igba iwase, ti awon olorin ba lo sere ni ilu kan, ka so wi pe won lo wuye oba tuntun to je ni ilu naa. Ti won ba tun lo si ilu miiran lo ba won se ayeye oku agba, ohun to sele ni ilu ti won ti sere keyin maa n jeyo ninu orin won nibikibi ti won ba de.
Ti ko ba si ti awon olorin ni, ko ni si iroyin okeere ati tetile.
Bakan naa ni a tun ri awon olorin ti won maa korin kiri aaarin oja nlanla laye atijo. Gbogbo ohun to si n sele layika ati layida won si maa n jeyo ninu ato orin won.
Kilode ti a fi gba wi pe ise iroyin aye atijo lagbara ju aye ode oni lo?
Nje awon olorin ode yii ti le n tesiwaju ninu ise iroyin gege bi ti aye atijo?
Olayemi Oniroyin ti mo ba da duro nibi sebi ara ni mo fi da, alaye ti ko ti tan sebi alaye re tun ku seyin jaburata ni.
E ku Ikale
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment