Smiley face

D'banj N Mura Ati Se Ayeye Odun Mewaa Ninu Ise Opolo Orin Gidi To Gbamuse

Ojo Kesan-an osu kefa (June 9) odun 1980 ni won bi Dapo Daniel Oyebanjo ti gbogbo eniyan mo si D'banj ni Zaria to wa ni Ipinle Kaduna.

Mr Endowed bere lati mu ise orin kiko ni gidi lodun 2004, eleyii to si ti sise papo pelu orisiirisii awon agbaoje olorin lagbo amuludun.

Lara awon ti Koko Master ti jo gbe ise opolo sori ate ni Wande Coal, Kanye West, Olamide, Snoop Dogg, 2Face Idibia ati opolopo awon mii.

To ba je nipa ami-eye, gambari se die ninu gooro ki ehin to pon bi eye aparo. Skibanj Eja Nla naa gbiyanju koja waza. Lara awon ami-eye ti Banga Lee gba ni :

Best African Act ti MTV Europe Music Awards 2007,

Artist of the Year ti MTV Africa Music Awards 2009 ati

Best International Act ti BET Awards 2011.

Nibayii, D'banji ti n mura lati se ayeye odun mewaa ti Olorun oba ti n gba fun un lenu ise orin to yan laayo (bi o tile je wi pe o tun ni awon okoowo mii to n se).

Odun 2014 ni ayeye naa yoo waye. Lagbara Olorun, gbogbo wa la maa wa laaye.

Olayemi Oniroyin si n fi asiko yii ki Igwe fun jije alaseyori ninu ise orin kiko. Iwaju lo je, Edua ko ni je ko wa sile lailai. Amin
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment