Ni nnka bi ose melo kan seyin ni awuyewuye kan gba igboro wi pe Mide Funmi Martins ko gbe papo mo pelu oko re ti won jo n se ise tiatia, Afeeze Owo ti gbogbo eniyan mo si Sarki Olopolo.
Nibayii, Mide Funmi Martins ti fesi ranse wi pe aheso oro lasan ni awuyewuye naa ki sooto oro gidi.
Adura wa naa ni wi pe ko ma je otito. Kini ere ara ilu ninu ki igbeyawo won tuka?
Sugbon oro awon agba lo wi pe isele kii se ko ma seni loju firi. Bi o tile je wi pe oro okeere bi ko ba le a maa din.
Ju gbogbo re lo, bi eniyan ba bu oba leyin to ba de iwaju oba to ba ni ko ri bee. Awon agba a maa gba wi pe ko ri bee naa nu-un. Niwon igba ti Mide ti kede wi pe iro ni oro naa, e je ka gba wi pe iro ni ohun ti awon eniyan wi pe o sele.
Eti to ba gbo alo, o ye ko gbo abo. Abo mi re ooo.
Home / Uncategories / "Ebe Ni Mo Be Araye E Maa Tapo Sala Mi" Mide Funmi Martins Ti Fesi Ranse Nipa Igbeyawo Re Ti Won Lo Ti Daru
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment