Smiley face

OJB Jezreel Fi Ijo Jijo San Die Ninu Ore Olorun Ni Ilu Ghana

Eni odun ba ba laye ko maa dupe.

OJB fese rajo lati fi dupe si Olorun oba fun iwalaaye nibi orin keresimesi ti ile ise iwe iroyin Magasiini Ovation gbe kale ni Accra ni Ilu Ghana.

Oun ati iyawo re, Mama J ni won jo wa nibi ayeye naa.

Iyawo re yii kan naa lo wa pelu re ni ilu India nigba ti won se ise abe fun OJB. Oun kan naa lo fi kidirin kan kale ninu kidirin re lati fi gba emi oko re la lowo iku.

A ba won dupe lonii nitori wi pe odun ayo ni idile won se, won ko sodun ibanuje.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment