Smiley face

Kini Seun Ogbere Se Ti Won Fi Pa Ni Ipakupa Ni Ilu Eko?

Ose to koja ni isele yii sele ni agbegbe Yaba to wa ni ilu Eko.

Omokunrin kan ti won n pe oruko re ni Seun Ogbere ti inagije re si nje Shaggy ni awon kan sekupa ni ipakupa ti enikankan ko si mo kilo fa sababi.

Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, agbo wi pe omokunrin ti oruko re nje Shaggy ni olori awon omo igboro kan ti won n pe ni 'Shaggy Boys'.

Ohun ti a tun gbo ni wi pe omokunrin naa tun ni ajeri pataki fun ejo apaniyan kan ti won da ni ile ejo lowolowo.

Osan gangan ni awon kan surubo Shaggy, ti won si bere si ni fo igi mo lori nigba ti awon kan n jin nigi nikun titi won fi gba emi lenu re.

Awon eniyan to wa lagbegbe naa to ye ki won gba sile, onikaluku juba ewoho ni nigba won ri bi won se n se Shaggy.

Igba to pe die ti awon to pa Seun ti lo tan, ni awon ebi re yoju. Okan ninu awon ebi re si n sukun to si n pariwo wi pe:

'Kayode ti pada pa mi legbon, ewo bi Kayode se pa egbon mi'.

Awon olopa lo pada wa gbe oku Seun.

Ti iroyin tuntun ba te wa lowo, e o tun maa gbo.

Ki e ni ojo rere!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment