
Awon Yoruba ni 'mi o gbo iru eleyii ri' eru la fi n da ba oloro. Sugbon otito ibe ni wi pe iru isele yii tun joni loju gidi gan-an ni.
Okunrin kan ti oruko re n je Adeji ni won ti n fi kondo olopa fun lomi mu bayii ni ago olopa Iyaganku pelu bi o se fi tipatipa ba obirin oloyun osu meta ti won jo n gbe adugbo sun pelu tipatipa.
Mary eni odun metalelogun(23) ti o diwo-dise simu ni eni ti isele buruku yii sele si nigba to n bo lati odo to ti lo pon omi ni abule Sanusi to wa ni Idi-Ayunre ti ilu Ibadan.
Oju igbo ni Adeji bo Mary mo, to si bere si ni kona boo labe leyin ti Mary ti rawo ebi si wi pe ko saanu oyun osu meta ti oun gbe sikun. Igba ti ina elentiriki Adeji wale tan, lo ba juba ehoro.
Owo awon olopa ti te Adeji booda olomi iye labe to fi tipatipa ba adelebo olomo meji sun leba odo.
Awijare Adeji naa si ni wi pe ololufe oun ni Mary lati ojo to ti pe.
Bakan naa la tun gbo wi pe oko Mary ti fi igba kan fi ejo Adeji sun awon agbaagba ilu pelu bi o se maa yo iyawo re lenu ni gbogbo igba wi pe oun nife re. Awon agba adugbo si ti kilo fun Adeji wi pe awon ko gbodo tun ri pelu ayaalaya mo.
Iwadii si n lo lowo, aimoye ohun to pamo ni a lero wi pe yoo pada fi oju han sode. Mary wa ni osibitu Oluyoro to wa ni ilu Ibadan nibi won ti n se itoju re.
0 comments:
Post a Comment