Emi o so wi pe emi o fe o mo.
Ololufe maa gbo.
Igba meta nigba eda laye.
Ika eniyan ti fogba,ki la fe fi bomi lodo?
Won ti kan epo soju omi,
Epo kinkin ti boju omi je.
Emi o so wi pe emi o fe o mo.
Otutu mu mi lale ana mo si sunkun.
Aya mi ja, eru ba mi nigba ti iji ja.
Mo ranti re mo si se idaro ife otito.
Emi ko, awon aye lo wu iwa ika.
Bawo lerupe se denu iyo?
Won ti da kaun somi
Won ti ri ife mole bi isu ewura.
Ololufe mi,
Emi o so wi pe emi o fe o mo.
0 comments:
Post a Comment