
Ohun iyanu sele ni ilu Kenya nigba ti oku ji dide ni ile igbokusi leyin igba ti ile iwosan to ti n gba itoju kede re wi pe o ti koja sorun aremabo.
Ogbeni
Paul Mutora eni to gbiyanju lati seku pa ara re nipa jije majele, ni ile iwosan Naivasha kede re wi pe o ti ku ni Ojoru eleyii ti awon eniyan re si jeri si i ti won si bere si ni lo seto isinku re.
Sugbon lojo keji to je ojo Alamisi ni awon osise ti won n sise ni ile igbokusi ti ile iwosan naa gbo ti enikan n mi gulegule bi eni oko jaale ninu kolo ti won gbe oku si eleyii to koko je iberubojo ti gbogbo osise si fon danu ko ti di wi pe won pada wa se ayewo leekansi.
Gege bi ile ise iroyin BBC se so, okunrin naa ti toro aforijin lowo ebi ati ore pelu bi o se ko gbogbo won sinu ikokansoke ati ibanuje.
0 comments:
Post a Comment