![]() |
| Ellen lori eto |
Bayii la n se ni ilu ti wa, eewo ibo mii ni. Sebi eegun ni gba owo ode ni ilu Osogbo. Bi ilu Ilorin ti tobi to, won o leegun.
Nikete ti ilu California fi owo si abadofin eleyii to pada di ofin wi pe abo meji (obirin ati obirin) tabi ako meji (okunrin ati okunriin) le fe ara won gege bi toko-taya ni Ellen DeGeneres to je sorosoro ori telifisan agbaye to wa ni ilu Amerika ti kede ati se igbewayo alarinrin pelu ololufe re, Portia de Rossi to je oserebirin.
Nibayii, toko-taya yii ti ko owo bi Ogoji Milionu owo dola ile Amerika ($40 million) ra ile nla agba-iyanu kan si ori oke Holmby to wa ni Los Angeles.
Yato si eleyii, Ellen to je oko tun ra moto Land Rover Defender tuntun eleyii ti iru e ko wopo fun iyawo re, Portia De Rossi ni kopekope yii.

















0 comments:
Post a Comment