Smiley face

Ile Ejo Ti Ran Akeemu Lewon Ni Ilu Oshogbo

Ile ejo Magistrate to wa ni ilu Oshogbo ti ran Akeem Ibrahim eni odun mokandinlogbon(29) lewon latari bi o se fi tipatipa ba omobirin omo odun meji lajosepo.


Onidajo Olusola Aluko lo da ejo yii lana ode yii niwaju gbogbo aye.

Gege bi oga Olopa Insp. Fagboyinbo Abiodun ti won mu Akeemu wa si ile ejo se so. O ni Ogbeni Akeemu 'Onisan-Labe' fi isan ba omo odun meji sun ni ojo keji osu keji odun yii, ni nnkan bi aago kan osan ni agbegbe Fagi Isale Afon to wa ni Ikirun ni Ipinle Osun.

Bi o ti le je wi pe agbejoro fun Ogbeni Akeemu be ile ejo wi pe asise ni ohun ti Akeem se ati wi pe ko ba dara ki won tu sile. Sugbon onidaju ko lati gba oro enu agbejoro Akeemu.


Gege bi oro re, oni ki Akeemu si lo maa mu gari ni ogba ewon naa titi won yoo fi gbe igbejo re dide lati mo iru idajo to ye fun un.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment