Aimọye
ìgbà ni mo maa n rò ohun ti mo le fi isẹ́ iroyin we. Awọn ohun tó jọra pẹ̀lú
isẹ́ iroyin tó wà ni awujọ wa jẹ ohun to maa n fun mi ni òye nipa orisii Isẹ
Iroyin to gbamuse ati ipo to yẹ ki isẹ iroyin wa gan-an ni gidi. Sebi ohun to
ba jọ ara won ni a fi n wéra wọn. Awọn Yoòbá ni won se apejuwe bi èpo ẹ̀pà se
fara jọ póósí ẹ̀lìrì. Eniyan to ba fi ori ológbò se apejuwe àmọ̀tẹ́kùn, a kò le
pe irú ẹni bẹẹ ni amukunmẹ́kọ lailai.
Lára ohun
tó yé mi yékéyéké nipa isẹ iroyin ni wi pe, isẹ iroyin tayọ ọgbọ́n àtinúdá
lasan gẹgẹ bi orisii ẹ̀bùn kan pataki ti àwọn onkòwe alatinuda gbámú gẹgẹ bi
ohun amusagbara gbòógì. Isẹ Iroyin jẹ akojọpọ èròjà lati àwùjọ eleyii ti a kó padà fun àwùjọ nipa ọgbọn atinuda ati
ète isẹ iroyin yálà lati fi salaye ọ̀rọ̀, isẹlẹ tabi lati tan ìmọ́lẹ̀ si òye
awon eniyan nipa awujọ ati ìgbé ayé wọn lapapọ.
Eyi tunmọ
si wi pe oniroyin ti ko ba rínú-róde nipa awujọ, bi oye rẹ tabi imọ rẹ ti wulẹ
ko jin to, àsàdànù ni iroyin wọn yoo pada jẹ fun awujọ.
Lára ohun
to tun farapẹ́ iru eleyii ni ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni awon ile ẹkọ wa gbogbo. Ẹ̀kọ́ kò ye
kó dúro lórí pataki ati ni ìmọ̀ lasan bíkòse orisii imọ lati yanju isoro to wa
ni awujọ wa. Eyi tun mo si wi pe orsii agbekalẹ ẹkọ ni ile ẹkọ gbọdọ kun fun
èròjà ti awon onímọ́ kójọ lati awujo. Iru awon eroja bẹẹ le jẹ ìsòro ti awujọ n
ko ju ni awon àyè kan. Agbekalẹ imo ni ile ẹko lati yanju isoro ti awujo n kojú
yoo si dabi èsì ti awon onímọ̀ fi ranse pada si awon agbegbe ti won ti se awari
eroja isoro awujọ nigba ti awon akẹ́kọ̀ọ́ won ba gboyè lori
orisii imo bẹẹ.
Bi ọ̀rọ̀
mi ko ba ti ye yin, a jẹ wi pe àlàyé mi ni ẹ kò ti ka tan délẹ̀délẹ̀. Sebi won
ni enikan ki i jiyan bi ọsẹ hó bì hó lodò. Níwọ̀n ìgbà ti àyàn mi ko ti ju
kọ̀n-ọ̀ngọ́ ilu silẹ̀, a jẹ wi pe awọ ewurẹ ti n fọhun si lohun pupọ lati sọ
ni.
Bi awon
aláàtò tabi alamojuto ẹ̀kọ́ se padanu ninu isẹ won nipa agbekalẹ ẹ̀kọ́ to
yanranti lati yanju ìsòro awujo nipa ironilagbara awon akẹkọọ nipa síse
agbekale orisii ẹkọ to peye to si ba ìgbà mu, awon eniyan awujo ko sai dákún
ọrọ naa nipa aini akiyesi to gbọn-ọngbọ́n nipa aye òde òní eleyii to yàtò si
ayé àtijọ́.
Ìgbà ti
mo wa ni pínnísin, nigba ti awon tó jẹ́ bi ẹ̀gbọ́n si mi ba n mura ati wọ ile
iwe giga. Awon òbí wa maa n tari awon ẹ̀gbọ́n wa si awon tó jẹ́ bi ẹ̀gbọ́n si
àwọn naa lati là wọ́n lọ́yẹ̀ lori orisii ìmọ̀ ẹ̀kọ́ to munadoko, eyi to le mu
won di ohun àdùrà lọ́jà (awon eléèbó ani hot cake) ti won ba jade ile ẹkọ giga.
Awon
ẹ̀gbọ́n àgbà yii naa o wa pelu àkójopọ̀ awon ẹ̀kọ́ orisiirisii ti eniyan le kọ
ni ile iwe giga to le tètè muni goke agba ti eniyan ba jade ile iwe.
Ọpọlọpọ iru akojopọ bẹẹ lo maa n bẹrẹ
pẹlu Ìmọ̀ Ìsègùn Oyinbo, Imọ Ẹrọ, Imọ Ẹro Ayabiasa, Imọ Ilé Kikọ, Imo Ise
Amofin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bi o tilẹ
je wi pe mi ò ni anfaani lati gbe pẹ́rẹ́gi èrò mi kaná níwájú awon ‘ẹ̀gbọ́n-
àgba-agbani-ni-ìmọ̀ràn-tó-péye’ yii, sibẹsibẹ n ko ni i lo babalawo adifala ki
òyé to ye mi wi pe orisii ẹ̀kọ́ yòówù ti eniyan le ko ni ile iwe kọ ni ẹ̀rí
tabi idaniloju ati tete moke ti eniyan
ba ti jade ile iwe.
Amúkùn-ún
ẹrù ẹ wọ, oni oke lẹ n wo ẹ wo lẹ. Awon akẹkọọ gboyè to ye ko jẹ atunse si
isoro awujo tun pada wa jẹ aleekun isoro ti awujo tun wa atunse si. Isẹ Iroyin
to yẹ ko jẹ àfọ̀mọ́ awujọ wa ni ohun kan pataki ti n si awon eniyan lọna.
Nitori pupọ ninu awọn oniroyin ri isẹ iroyin gẹgẹ bi Akéde sugbon ise iroyin
ki i se isẹ akade.
Olayemi,
ki ẹ to da mi lẹjọ wi pe alaye mi kò ta létí. Kẹ ẹ to fẹnu àbùkù so wi pe ẹnu mi
n run fáròyé. Ẹ o ba duro ki n wakọ̀
àlàyé mi ti síbì kan ná. Ẹ se suuru ki n sọ̀rọ̀ kẹ ẹ to se ìdájọ́ mi ni gbangba. Titi maa fi pada pẹlu alaye
mi, mo fẹ kẹ ẹ ro ipalara to seese ko waye fẹ́ni ti ko ti jókóò ko nasẹ̀ to n
sáre ati fèhìntì.
Ọlayẹmi
ni baba mi sọmi, ọjọ tinu rẹ ba dun ni i pe mi ni Al'Ayinba Ọba. Oni Ogúnjọ́
Osù Keji lo pe ọdun merindinlogun t'Akanji ti lọ ti o pada wa saye mọ.
Akanji Òdí Ará Ìrẹsà. Sun Re!
E le ka Apa Keji [NIBI]
Akanji Òdí Ará Ìrẹsà. Sun Re!
E le ka Apa Keji [NIBI]

Opolo yin ko ni joba. Olorun alagbara yoo tun bo maa fun yin se. e ko ni i siso, e ko si ni sile te. Amin
ReplyDeleteOniroyin Agbaye, E ku ise ooo. Olorun a tunbo maa fun yin se si.
ReplyDeleteOlorun a ko saanu fun wa ni orile ed yii.Emi gba wi pe gbogbo iya to n je wa maa dopin lojo kan. Awon to je olori wa ni won ko bbikita fun awon odo ati mekunu. Oloruun a saanu fun wa o
ReplyDeleteAmin o. E se gan-an
ReplyDeleteMay His Gentle Soul Rest in Peace. Keep it up. You are the best
ReplyDeleteAppreciate. You are wonderful too. Thanks
ReplyDeleteOlayemi Oniroyin mmmmmmmmmmmm. Well done man. I dey feel am well well
ReplyDelete