Smiley face

Ise Aye Ti Mu Oko Iyawo Dana Sun Iyawo Re Pelu Oyun Ni Ilu China

Oro naa jobi eedi tabi ka pe ni asasi, nigba ti awon ka gba wi pe oseese ki ori Li Moulian eni odun merindinlogoji (36yrs) ti yi danu. Guusu ilu China ni isele yii ti waye nibi ti Li Moulian ti gbe sadeede ki iyawo re eni odun mokanlelogun (21) pelu oyun inu mole lati lo dana sun won loju olomo-o-to.

A ti ori beedi ni Li Moulian ti wo Xu Fan to je aya re sile, leyin eyi lo di bi igba ti gambari ba di eru ti n re oke oya, lo ba lo de mo eyin moto o si bere si ni wa kiri igboro Huizhou to wa ni Guangdong.

Gege bi ase gbo, kii se wi pe toko-taya yii fe ara won nisu-loko gan-an, won kan fun ra won loyun ni won si bere si ni gbe papo.
Leyin osu mefa ti awon mejeeji ti n fera won, o jo bi eni wi pe igbeyawo naa ti su oko iyawo, o si ro wi pe ona a ti fi opin si ajosepo naa ni lati seku Xu Fan to je aya re.

Igba ti okunrin yii de ikorita kan, o duro. Ikorita yii lo ti bere si ni fe afefe gaasi (gas) si obirin naa lara. Nibi to ti n se eleyii ni awon olopa ti awon kan ti kesi nigba ti okunrin naa n di iyawo re sinu moto bi eru ti de ba won.
 

'As the police car with a siren approached the car with the man and woman inside, and another blocked off its escape route from the rear, the man ignited something in the car which exploded into flames.' Alaye awon olopa

Ina ohun ko si jo Xu Fan nikan, o pada fe lu oko re naa. Koda, ina to jo oko ju ti iyawo lo ki awon olopa to wa gba emi awon mejeeji la kuro lowo iku iparun. Awon mejeeji si ti wa ni osibitu bayii.
 
'We had warned her that she needed to know more about him before deciding to spend her life with him, it seems sadly the warnings were true as he clearly has mental problems.' Alaye Wu Chin to je egbon Xu Fan.'


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment