Awon eniyan bi ogorun ni won ti bo mole lana (26-06-14) ni guusu ilu Kaduna.
Awon eniyan yii ti opolopo won je omode ati obirin ni won se agbako iku nipase ikolu awon omo agbegbon kan ti won yalu awon abule bi marun-un to wa ni Ijoba Ibile Sanga ti Ipinle Kaduna.
Gege bi a se gbo, aimoye awon eniyan ni won ti di awati bayii nigba ti awon eniyan bi oodunrun (300) ti di alabarapa.
Okan ninu awon omo ilu naa ti o pe oruko ara re ni Sunday Ugah se alaye fun awon oniroyin wi pe lati nnkan bi ogoji odun seyin ti won ti bi oun, oun ko ri iru isele buruku bee ri.
"Mo ri idile kan soso ti won padanu gbogbo omo mejila ti won bi patapata" Sunday
Ojo Isegun ati Ojoru ni awon kan ti won fura si gege bi omo Fulani ni won yawo awon abule ta n soro re yii ti won si bere si ni pa awon eniyan bi eran ileya.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment