To ba ku die ki omo oloore jin si koto, monamona yoo sise imole. Tanu, omo odun marun-un kan ni ilu India ni awon kan ninu ebi re gbimo po lati sin laaye.
Sugbon Edumare sise iyanu nla, ki emi to jade tan lara omobirin kekere naa, Baba mimo ran oluranlowo sii.
Okunrin alaanu Samaria kan ni i koja lo, ibe lo ti gbo igbe omode naa to si to ipase re lo. Ibi to ti n to ipase omo naa lo lo ti ri iyepe ti n ru soke bi eni wi pe nnkankan n gbinyanju lati jade.
Igba ti okunrin naa yoo fi wa iyepe naa kuro, Tanu omobirin eni odun marun-un lo ba to ti daku ki won to gbe lo si osibitu.
Oro ti de odo awon olopa bayii lati mo awon ti won se ise ibi naa.
0 comments:
Post a Comment