Adewale Dada TheGood si n tesiwaju ninu ipinnu re lati ri
ifowosowopo awon eniyan ti won n gbe ni agbegbe Sango Ota ni Ipinle Ogun
ninu eto idibo odun 2015.
Die lara alaye to se nibi
ipade kan lana, Ojo Aje [1-9-14] pelu awon oloselu, Alao se alaye wi pe
oselu kii se ona tabi anfaani lati ko owo ilu sapo bikose ona tabi
anfaani lati tun igbe aye awon eniyan awujo se si rere.
Wale
Dada so iriri re pelu awon ilu okeere bi Amerika ati UK eleyii to ri
nigba awon irin ajo re si awon ilu naa. O si pinnu lati mu iru awon
nnkan idagbasoke tuntun bee naa wa si agbegbe Ota.
Okunrin
ti won fun ni ami eye sorosoro ori redio to tayo ju lo fun odun 2014 ni
Ipinle Ogun so wi pe ironilagbara (empowerment) ni yoo poju ninu awon
igbese oun nigba ti awon eniyan ba le ti oun leyin doke.
Bakan
naa lo tun se afikun agbekale kan eleyii to pe ni Personal Encounter.
Eleyii ni awon eniyan ti won ko reti ore sugbon ti won yoo di olorire
ojiji latari wi pe won pade Omo Dada.
Lafikun, TheGood
se alaye wi pe eni ti n be Olorun kii be eniyan sugbon o gbodo maa se
aponle awon eniyan. Oro ologbon yii mu inu awon eniyan dun won si bere
si ni korin tijo-tayo. Ninu orin won ni won si ti bere si ni kede
TheGood gege bi olubori.
Ati ibi ipade yii ni Awon
ololufe TheGood lori redio Faaji FM to wa ni ilu Eko ti n pe e lori ago
wi pe awon ti n reti ololufe awon.
Lori eto BALE LAYO,
eleyii to maa n waye laaarin ago marun-un si meje ni agbaoje naa ti tu
kasa ede ogbon ati awada sile bi igba eniyan si awon adiye sile ninu ago
ti won si bere si i fonka kaakiri agbegbe patapata.
Alao
so wi pe bi ohun ta o je senu bi ounje se se pataki to, a ko gbodo je
ki ohun ta o je senu di wa lona nipa ohun ta a fe je leyinwa ola. Iru
eniyan ta a fe je se pataki ju iru ounje ta a fe je senu lo.

0 comments:
Post a Comment