Smiley face

Orin Se Rere Lati Owo Adewale Dada TheGood

Ko si ohun ti eniyan se laye ti ko lesan, ati ire ati ika ko si eyi to gbe. Lonii, mo se afihan ewi ti mo pe akole re ni Baba Kogbẹbọ ati okan lara orin Adewale Dada TheGood to pe akole re ni Se Rere. E ku Ikale. 

BABA KOGBEBO 

Lori oke ọkan yii naa ni.
Sáájú ko to dohun àjíkì.
Sebi won ni bọmọde kò bátàn...
Àtìtàn atarọba le mi yan bi ẹran lórí ayanran.

Sekaseka boo ba leti gbọ mi lonii.
Aya koko inaki, alaya bi esu.
O n sise ibi won sàà ọ o tun dun nú.

Lori oke yii naa ni.
Jagilegbo soogun joojumọ nisẹ ibi.
Oró dídá ni fi n sọla.
Baba ologun ìkà ti won pe Kògbebọ.
Ada ò ran, ibọ ọ ran bẹẹ ni i daye laamu tiyọnutiyọnu.

Ori oke ọkan yii naa ni.
Nibi o ti n jáwé amuseka.
Kogbẹbọ yẹgẹrẹ ẹsẹ lo ba fori napata.
Gbogbo purapita apa ba pin.
Ewo bi Ọba oke gba mu ika eniyan.
Isu dilẹ leyin asunsu jẹ.

DONWLOAD Se Rere by Adewale Dada Thegood
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment