Ojo buruku esu gbomimu lana [28-11-14] je fun Aare Jonathan ninu ogba ile iwe Obafemi Awolowo University to wa ni Ile Ife nigba to se abewo si ile iwe naa leyin ipadepo pelu awon agbaagba ile Yoruba nibi ti won ti fonteluu gege bi Aare odun 2015.
Bowo ni ana ko ba ti dun to fun oko Patience to ba je wi pe ilu Abuja lo gba lo taara leyin ipade naa. Sugbon gege bi won ti so, ori ti o jeya ko ni salai ma rin lo sibi ti won ti jin ni kondo lori.
Ole, tiifu, barao ni awon omo ile iwe naa n pe Jonathan. Orisiirisii akole ni won si gbe dani pelu. Lara akole naa ni eyi to n bu enu ate lu bi ijoba se fi owo le owo ile iwe won ati bi iku gbigbona se pa awon omo ile iwe ni ilu Jos. Yato si eyi, awon akole mii tun so nipa bi ina eko se n jo ajoreyin labe isejoba Aare Goodluck Ebele Jonathan GCFR.
Lara awon to tele Aare ni Ooni ti Ile Ife, Alayeluwa Oba Okunade Sijuade ati Gomina ti Ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Foyose.
Ori moto Ooni ni awon omo ile iwe naa ko ko mugun ti won si bere si ni fosoke bi igba ti won jo alanta. Igba oro di isu ata yan-anyan ni Fayose ni ki Aare Jonathan mokan bale wi pe oun mo bi oun yoo se kontiro awon omo ile iwe OAU naa ti won kagidi bori bi faanu Taiwan.
Bi Fayose se yoju bayii ni awon omo ile iwe tun pariwo "Ooooooole". Fayose ba sare sa pada seyin.
Igba oro bo sori, n se ni Aare sare pada lo wo inu baalu erokoputa re. Koju ma ribi, gbogbo ara loogun re.
Bi Aare se n sare lo ni awon omo ile iwe naa n le ni okuta, awon kan le ni ogulutu, awon kan si n so idaro lu baalu re.
Ana o da o, ana kodun, walahitalahi ana buta soju fun Jonathan gidigidi.

0 comments:
Post a Comment