Smiley face

Boko Haram Ju Bombu Si Mosalaasi Lojo Jimoh Ni Ilu Kano

"Awon eniyan bi igba (200) lo sofo nibi isele ijamba ado oloro naa", alaye eni oro soju re.

Awon omo alakatakiti esin ti a mo si Boko Haram ju ado oloro si mosalaasi nla Centra Mosque ti ilu Kano nibi ti Emir Kano ti n kirun Jimoh lojo Jimoh to koja yii [28-11-14].

Sugbon ori ko Oba Kano yo nitori ko si nile ni akoko naa, ilu Mecca lowa nibi to ti n gbadura fun alaafia Nigeria.

Ado oloro yii lagbo wi pe o dun nigba awon eniyan ti pejo lati kirun Jimoh.

Titi di akoko yii, enikeni ko ti le so pato iye awon eniyan to ku ati awon to farapa, sugbon akiyesi fi ye wa wi pe aimoye emi loso ni ile Oluwa naa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment