Otunba Akolawole Olootu le lodun lonii ojo kerindinlogun osu kokanla odun [16-11-14], Olayemi Oniroyin fope fun Eledumare Oba Mimo.
Lara idunnu mi si ni lati so die lara ohun ti opolopo ko mo nipa Baasoro Ile Yoruba.
*"Olootu" ti Kola Olootu n je kii se oruko abiso tabi oruko baba re. "Olootu" dabi oruko ori itage bi igba ti a ba n so wi pe Saheed Osupa, Alabi Pasuma, Sule Malaika ati bee bee lo. Kolawole Olawuwo Adedokun ni apeja oruko Otunba Kola Olootu gan-angan.
Igba ti Kola Olootu bere ise sorosoro, Kola Olawuwo gan-an ni oruko ti n je. Sugbon nipa wi pe Kola Olootu ati Kola Olawuyi fi ohun jora, awon eniyan bere si ni si won mu si ra won.
Oruko won tun fe dabi eni wi pe o fe dun leti bakan naa: Kola Olawuyi- Kola Olawuwo.
Kola Olootu pinnu lati yii oruko re pada nigba ti pupo awon eniyan ti won ba fe gbe ipolowo oja fun Kola Olawuyi sina gba odo Kola Oootu. Sugbon ninu alaye awon onibara, ti Kola Olootu ba se akiyesi wi pe Kola Olawuyi ni won fe ri, yoo dari won si Kola Olawuyi pelu alaye wi pe Kola Olawuwo ni oruko ti oun je. Igba ti asise yii n po, ni Kola Olawuwo yi oruko re si Kola Olootu.
*Awon orin ipolowo oja lasan ni Yinka Ayefele n ko nibere aye re nigba to n sise ni ile ise radio. Kosi fi igba kankan ni lokan lati se rekoodu orin ariya ti awon eniyan yoo maa ra kaakiri jade.
Sugbon igba ti Olayinka Joel Ayefele ni ijamba moto, M.O.N niilo iranlowo owo lati lo si oke okun fun itoju to peye. Yato si owo tabua ti Kola Olootu gbe kale, oun ni eniyan akoko to gba Yinka Ayefele nimoran lati se rekoodu orin jade pelu ileri lati se igbelaruge ati ipolowo fun rekoodu naa ti yoo fi di itewogba fun gbogbo aye. Bi Yinka Ayefele se bere re e to si di irawo kari aye.
*Lara awon fiimu to so Saidi Balogun di irawo olokiki lagbo amuludun Nigeria ni "Olongbo Dudu" lati owo Kola Olootu. Ninu fiimu naa ni gbogbo aye ti mo Saidi si Walata (Wale Walata). Doris Simeon si ti salaye wi pe alubarika to tele fiimu akoko ti oun kopa ninu re, "Ago Kan Oru" lati owo Kola Olootu wa lara aseyori oun laye.
*Odun 1984 ni Kola Olootu Productions ti fidi mule. "Oselenkejo" to je eto Kola Olootu lori redio lo je eto Yoruba to pe ju lo lori afefe ni ile kaaro-o-jiire.
*Kola Olootu je sorosoro ori afefe to rin irin-ajo losi oke okun julo laarin awon akegbe re. O si feran ko maa ra awon irinse igbohun safefe orisirisi pamo niwon igba ti o ba lo si awon ilu okeere. Iwadii tile fi ye wa wi pe Kola Olootu ni irinse igbohun safefe ti o le fi da ile ise radio sile. Ohun meji ti ko ni ni alatagba (Transmitter) ati iwe ase (licence) eleyii to nira lati gba lowo ijoba.
*Kola Olootu je eni to maa n sawada lopolopo. Eniyan ko le wa legbe re ko banuje. O ko awon eniyan mora lai fi tesin se, o si je olusin Olorun nitooto.
*Bi omode tabi omoleyin ba ki Kola Olootu, igbakigba kowu ko je, gbolohun kan pere ni omo Adabanija feran lati fi maa da won lohun: "Adua re o gba".
Kola Olootu feran gbolohun naa pupo. "Adua re o gba" je gbolohun ti ko le ma jade lenu re laimoye igba lojo kan soso.
Aimoye nnkan ni mo fe salaye nipa Kola Olootu, sugbon ma duro nibi lati tesiwaju lojo iwaju. Oni ni ojo ibi Kola Olootu, Adura mi ni wi pe ko pe laye ninu alaafia, ogbon, imo, ola ati ayo.
Happy Birthday King of Radio!
Mo ba olojo ibi yo, mo si ba a dupe lowo eledumare. Igba odun, odun ka ni ooooo.
ReplyDelete