Smiley face

“Inu mi dun wi pe mi o jawe olubori gege bi gomina” – Alao Akala

Alao Akala

Gomina ipinle Oyo nigba kan ri, eni to tun dije fun ipo gomina ninu eto idibo odun 2015, Oloye Adebayo Alao-Akala fi idunnu re han bi ko se jawe olubori ninu eto idibo gomina to koja. Oro yii lo jade nigba ti n kaanu awon gomina to wa lori oye pelu bi eto oro aje Naijiria se denukole, eleyii ti ko mu irorun deba isejoba won.


“Inu mi dun wi pe mi o tile wole gege bi gomina lodun 2015. Pelu ibi ti eto oro aje Naijiria de duro yii, afaimo ni ki jebete ma gbe omo le mi lowo ti mo ba je gomina. Mo yin awon gomina to wa nipo, nitori owo ti won rigba lati odo ijoba apapo ko to n se ohunkohun," oro yii ni Alao Akala so niluu Abuja nigba to n se abewo si olu ileese egbe APC.

Bakan naa ni Akala tun gba awon eniyan niyanju lati ma fa seyin nipa sise atileyin won fun egbe APC. Nitori dida lo da lomo fi degbe, egbe ki i se ile omo.

"Awon nnkan ta n la koja bayii fun igba die ni. A tile dupe, nnkan ti n pada bo si po. Mo si mo wi pe laipe, gbogbo ohun ta n fe ni yoo di irorun." Akala fi kun oro re bee.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment