Smiley face

Olori Wuraola ti bere ojuse re gege bi ayaba Ooni Ogunwusi



*Ewa, oge, ola, Olori Wuraola lekenka
Olori Wuraola
Gege bi isedale Yoruba, ibi taa ba ti ri ori ade, awon ayaba ki i gbeyin. Eleyii lo fojuhan pelu bi Olori Wuraola Zynab Otiti se duro gbagbaagba legbe Ooni Enitan Ogunwusi gege bi alejo pataki nibi ayeye Igbaniwole akekoo ti Kings University to kale si Ode-Omu nipinle Osun.


Tijotayo, tilutifon niluu Benin fi fa Wuraola Otiti kale fun Oba Enitan Ogunwusi Ojaja II lojo kejila osu keta odun yii (12-03-16) nibi eto ayeye igbeyawo to waye niluu Benin to wa nipinle Edo. Bi o tile je wi pe Ooni ko si nikale nibi eto igbeyawo naa sugbon Baba oba ati awon oloye ilu Ile-Ife soju Arole Oodua ti won si se gbogbo ohun to ye nipa bi asa ilu Benin se laa kale. Leyin eyi ni won mu Olori Wuraola Otiti wolu Ile-Ife nibi ogunlogo ti n duro lati woju olori tuntun laafin.

Laifi igba kan bokan ninu, okiki aseyori Oba Enitan Ogunwusi lati da alaafia ati emi isokan pada sile Yoruba lenu akoko perete ti Ojaja keji gori ite Odudua fi han gege bi ologbon ati onilaakaye eda. Eleyii ti akosile re ninu itan ko le parun laelae. Ni ti faari oge sise, Ooni asiko yii pegede. Arambara aso oge bi teye okin lomo Ogunwusi fi n logba. Ooni Ogunwusi Ojaja keji laa ba ma pe loba onile funfun ti n faso funfun dara oge. Awon awomo wonyii nipa Oba Ogunwusi ko je ko joniloju nigba ti gbogbo aye foju kan orekelewa aya Oonirinsa tuntun. Sebi eni mo iyi wura bayii la a fi i fun. Olori Wuraola pon winikinkin bi eebo. Bee lo n dan gbinrin bi ide. Awo ara re tutu minijojo bi eja aro gidigba lodo. Funfun ehin re ko yato si ti lekeleke oba efun. Bakan naa ni irin ese re si fi han kedere wi pe, orekelewa ti won bi nile ola ni i se.
 
  
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment