Smiley face

Jegudujera: Ile ejo siwe esun Saraki lakotun



Awon Yooba bo, won tina ko ba tan laso, eje ki i tan leekanna. Ibi aroko ti si, ibe naa la a fabo si. Eleyii gele ni se apejuwe aare ile igbimo asofin agba Abuja, Bukola Saraki, pelu awon esun ti ile ejo tiribuna CCT fi kan an. Igbejo yii lo tun waye lojo Jimoh ose to koja yii (11/03/16). Gege bi awon asofin ti won duro gege alatileyin Saraki ti n se bo lateyin , bi ogbon ni won duro ti omo Baba Oloye ilu Ilorin bi gbogbo won se n kowo rin wo inu kootu tiribuna CCT ni nnkan bi aago mewaa ku iseju merin aaro ojo Eti to koja yii niluu Abuja.
Die lara awon to kowo rin pelu Saraki ni igbakeji aare ile igbimo asofin,  Ike Ekweremadu,  Ben Murray Bruce, Stella Oduah, Hope Uzodinma, Shehu Sani, Dino Melaye, ati awon senato ti won lenu nibe nile igbimo asofin agba.

Saraki, eni odun metalelaadota (53), ni won fesun aisododo nipa ijewo dukia eni lojulowo fun ajo Code of Conduct Bureau ati awon esun jegudujera mii nigba to wa nisakoso gege bi gomina Ipinle Kwara.

Lojo Eti yii kan naa, loju ona agbawole si kootu tiribuna, awon odo kan ti won je ololufe Saraki gbe orisiirisii akole dani ti won si n pariwo, “e fi Saraki lorun sile”.

Lopin ohun gbogbo, ile ejo tun sun igbejo naa siwaju di ojo kejidinlogun osu keta odun yii (18/03/16) nigba ti Saraki yoo tun ma pada fojuhan lati wa se alaye enu re lekunrere.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment