Smiley face

Niluu Ile-Ife, Ooni yan Obalufe tuntun gege bi igbakeji re

Ogbeni Idowu Olaniyi Adediwura
Arole Oodua, Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi (Ojaja II) ti yan Ogbeni Idowu Olaniyi Adediwura gege bi Obalufe tuntun ti gbogbo ilu Ile-Ife pata. Igbese tuntun yii lo waye leyin ipapoda Oba Folorunso Omisakin to rebi agba n re lojo keedogun osu kewaa odun to koja yii (15/10/16). 


Adediwura ti awon afobaje Ile-Ife mu lati idile Ajagbusi lo da gbonmi-si-omi-o-to kale l’Ojoru to koja yii nigba ti awon idile oye yoku dide wi pe, awon ni ipo naa tosi. Awon idile oye merin ti itan isembaye se afihan re wi pe won leto lati je oye Obalufe, oye to kangun si Ooni Ile-Ife tabi ti a le pe ni igbakeji Ooni, ni Ajagbusi, Ado Gbodo, 

Aga ati Jaojo. Oba Omisakin to gbese wa lati idile Ado Gbodo nigba ti Obalufe tuntun si di yiyan sipo lati inu idile Ajagbusi. Ninu rukerudo to waye latari oye jije naa ni idile  Aga ati Jaojo ti gbe fesun riba gbigba kan Lowa, Obaloran, Obajio ati Jaaran ti won je igbimo afobaje gege bi won se se atileyan fun Adediwura lati je Obalufe.

Wayio, Aare Obalufe Progressive Youth Club, Omooba Arogundade Taiwo, je ko di mimo wi pe, gbogbo awon omo oye ti won leto si oye naa ni awon afobaje gbeyewo finifini, eleyii to si je wi pe, eni oye naa ye ni won gbe fun lai si wi pe enikeni figba kan bokan ninu.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment