Smiley face

Akanda eda ti won pe ni Jamal-Caleb Apena

Jamal-Caleb Apena
Oloju ẹni to jo mi loju, igberaga kọ
Oloju ẹda to le mu mi gbe ọpẹlẹ ewi sanlẹ
Beniyan o jọba tabi jẹjoye, Olayemi o ni kewi fun un.
Mo rekoja akotọbanu ninu ise orin gidi
Emi yato sọmọde akewi ti n kalolo ọrọ

Ina ti jo dori koko, asiko ni yii ti mo fẹ da orin ewi 'lẹ.
Tori ẹni meji kọ, tori Jamal-Caleb Apena ni
Onisẹ ọpọlọ to fakiki, anjaanu onisẹ alakada ti won pe bọ bi oke.

Oke ma ma wo subu, Apena  mbẹ lori àpèré dọla.

Jagunmolu ti n danilọgbọn oriire.
Ogboju onisegun imọ ti n gbani lọwọ aimọkanmọkan.
Oluko agba ti won yẹwo bi Ifa.
Peregede akikanju ti won kunle fun bi Ogun Ajọbọ.

Eni t'Apena ba ko lọgbọn iwe ti o ba jafafa.
Bonitoun soogun isoye, o fowo jona lasan ni.

Oni lọjọ ibi oluko to fọgbọn nla romi bi asọ.
Boo ba lo ẹgbẹrun odun laye, o ni jẹkoro laelae.
Igba ile rẹ ko ni fọ, awo ile rẹ ko ni faya.
Igba odun, odun kan ni fun ọ. Asẹ


#HappyBirthdayBoss



Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment