Smiley face

ẸLẸKỌ MayorKun n ta warawara bi ẹkọ


Mayorkun

Ti Edua oke ba ni asiko eda to lati goke, bi idan ni i ri loju ọmọ araye. Ẹda o laropin. Sebi oba oke nikan lo ni kadara ẹda lọdọ.  Bi awon ota ba gbena kari ti won ni ko ni pọsibu, ojo t’Oluwa ba da ba pe, awon ogun orun o so iru ina bẹẹ kalẹ ni.

Lati  ọjọ ti ẸLẸKỌ ti jade lo ti je wi pe, emi lorin meji mo ju ẸLẸKỌ lọ. Yato si agbekale orin to yaayi leti, isipaya ati ireti ogo kun inu orin naa dẹmudẹmu. Idi ni yii to fi jẹ wi pe orin MayorKun lemi n gbo ti mo ba fe sun ati ti mo ba ji saye.

Mayorkun, asiko re e, gbogbo igi ti elegbede rẹ ba fowo ba pata ni yoo ma dun korokoro seti omo araye.

Boya eyin ko tile ti i gbọ orin MayorKun, e le gbo orin naa NIBI bakan naa ni e le wo Fidio re NIBI

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment