Smiley face

Kini idi abajọ ti won fi n ki Oyo ni "Òjò pa sèkèrè módè omo Àtìbà"?

ÌTÀN TÍ Ó RÒ MÓ ÀFIKÚN "Òjò pa sèkèrè módè omo Àtìbà" SÍ INÚ ORÍKÌ ÒYÓ.
"Òjò pa sèkèrè módè omo Àtìbà"
Ní àkókò tí Aláàfin Siyanbólá Omo Olúkúewu jé Aláàfin ní ìlú Òyó, bàbá kan wà tí ó ní egbò kòndù lójúgun, egbò náà kéè dé ibi wí pé òórùn rè ni àwon ènìyàn rè lára tí wón sì kò ó tì láì náání rè.

Nígbà tí Aláàfin rí bàbá yìí àánú rè se é, ó sì pàse pé kí àwon èsó oba ó gbé bàbá náà lo sí ààfin. Ìtójú tí ó péye ni Oba sètò fún bàbá náà nípa bíbá a fo egbò rè tí ó sì tún fún un lágbo tí ó mú kí ojú egbò náà ó tètè gbe.


Yorùbá bò wón ní;" báwo bá kì fún ni, à á kì fún un padà ni". 

Àti wí pé yinni yinni níí jé kéni ó se òmíràn. Bàbá yìí be Aláàfin láti jé kí òun ó máa wà ní Ààfin kí òun sì darapò mó àwon tí ó n dá oba lárayá. 

Aláàfin gbà béè àmó ó sàlàyé wí pé onílù Ààfin ti pé béè òun ò ní fé kí bàbá yìí ó máa fi àgbà ara jó ijó àjólàágùn. 

Ni bàbá náà bá ro oba láti jé kí òun máa lu akèrègbè tí òun so owó eyo mo pèlú ìlèrí wí pé dídún rè yóò máa se régí pèlú ìlù, Oba sì gbà béè fún un.

Ó jé àsà Yorùbá pé bí oba bá jáde tí ó sì fé wo ìlú padà ìlù ni won ó fi kéde ìwòlú Oba, àmó ní ojókan báyìí tí Aláàfin Siyanbólá n ti àjò bò, òjò nla kan rò tí ó férè wú òkú òle, òjò yìí pa àwon onílù Aláàfin tìlùtìlù ni ìlù bá kò tí kò sì dún, kòngó sisé àmó awo ò fohùn. Irú ìjògbòn wo lèyí? Béè ni oba ò lè wòlú láì kéde rèé.

Orí ìrònú odó tí won ó da òrùnlá òrò náà sí ni wón wà tí wón fi gbó ohùn sèkèrè tí bàbá yìí n gbá. 


Ìdùnnú subú lu ayò fún àwon Akówòórìn Oba àti Aláàfin fún ra won, ni wón bá ní kí baba ó lèwájú kí ó máa lu sèkèrè nìsó tí àwon ìlú sì fi mò pé Aláàfin wòlú.

Inú Aláàfin dùn kojá kèrémí, ó sì fi ìmoore rè hàn sí bàbá yìí nípa pé ó so ó di pàtàkì láàrin àwon Amáàfindùn tí ó sì máa n wí pé; 

"Òjò gba ohun dùndún, ó gba ti bàtá gba ti gbogbo ìlù, sèkèrè nìkan lòjò pa tí kò dè tárá ìlú fi mò pé Omo Àtìbà wòlú"

Láti lè máa rántí ipa tí sèkèrè kó lójónáà lóhùn-ún ni wón fi fikún oríkì won wí pè 

" ÒJÒ PA SÈKÈRÈ MÓDÈ OMO ÀTÌBÀ"

Àbò mi rèé o. Opé pàtàkì lówó àwon èjìká tí kò jé kórùn ó yè, àwon àgbà tí wón kún mi lówó lórí isé yìí; Ìyáàgbà Adépèlé Àpínké àti Ègbón mi Àtàtà Alàgbà Adérèmí Ládìgbòlù. 

E Seun mo dúpé púpò oooooo.

Yorùbá ò ní di àtèmérè lolá Olódùmarè.


Orisun: ©Olùkó Èdè Yorùbá Arb (2016)
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment