Smiley face

Baasọrọ Ile Yoruba: Olubadan fi Kola Olootu joye

Baasọrọ Ilẹ Yoruba, Otunba Kola Olootu
Ka ma parọ, oloju alagbara to le gbe olumọ sare. Oloju ẹni le fọwọ lasan fọnna ayafi ẹni èdì ba n di tabi ko jẹ Sango olukoso ọkọ Ọya. Lati ilẹ yii to fi doke okun, oloju sọrọsọrọ to le wi igba ọrọ lete lai mu takada dani, a fi Sikiru ọmọ Olawuwo, Akolawole Olootu omo Adabanija, Baasọrọ Ilẹ Yoruba pata. 

Ẹni Akolawole Olootu ba polowo oja rẹ ti o ba ta, bẹni naa lori CNN agbaye iro lasan lo pa. Ọgbọn ori ko dabi ẹni oba oke fun se. Ka pede asayan ko dabi agbekalẹ to mọyan lori. Imọ si sàgbà ẹbun lọjọkọjọ, to ba jọ bi iro ẹni ẹ ba ri ẹ bi. To ba wa jẹ wi pe won gba kofẹsọ ninu ede pipe ni, Olootu ti to lẹni a ba maa jiki b’oosa.
Oba Saliu ati Olootu, nigba to ku diẹ ki baba gori itẹ
Bo tilẹ jẹ wi pe, o ti pe ti  Kola Olootu ti gbe oye Baasọrọ lori, sugbon Ọtunba ti lọ wuye oye naa bayii gẹgẹ bi agbekalẹ isẹdalẹ Yoruba niwaju Oba Saliu Adetunji Aje Oguguniso 1, Olubadan tilẹ Ibadan.
Kola Olootu ninu yara agbara
Ni oruko mi ati awon igbimọ mi pata, mo ki Baba Oloye ku oriire oye tuntun.

Oye a mọri o!
Baba oloye, Baasọrọ Ilẹ Yoruba
E wo awon FOTO ayeye naa NIBI
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment