Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (5)


#AyeOlabisi5
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (5)
Igba wo ni Maku ko ni ku?


Mo pinnu lati kọ leta ifis-silẹ mi silẹ loju ẹsẹ. Bi ọna kan ko di omiiran ko le la. Mo kọ lẹta mi yii, mo si fi pamọ wi pe ti o ba di ọjọ keji, ma lo fi le ọga alagbere yii lọwọ. Nigba ti o di aarọ ọjọ keji, mo ti lo fi lẹta naa si ori tabili rẹ ki o to de.

Leyin igba diẹ to ti de, ikan ninu awon osise ti won tun jẹ oga fun mi wa ba mi wi pe oga patapata ni ki n ko gbogbo ohun to wa ni ikawọ mi silẹ. Ati wi pe won ti ba accountant sọrọ wi pe ko fun mi ni ẹto to tọ si mi.

Eyi jẹ ki n mọ wi pe oloriburuku naa ti ka lẹta mi. Awọn ti won ko mo ibẹrẹ ọrọ lofiisi mi n bere idi ti mo fi fẹ fisẹ silẹ, awon to mo nipa rẹ ò lagbara lati gba mi sile lọwọ “Bashorun Gaa” to fẹ pa mi jẹ. Eni a ko le mu, Olorun laa fa le lọwọ. Emi ko tile reti ẹto kankan lọwọ won. Nitori mo ti pa okan mi po soju kan.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment