Smiley face

Awon nnkan ti e ko mo nipa oko tuntun Funke Akindele: JJC.

Eyi ni die alaye nipa oko tuntun ti Funke Akindele n fe bayii.

Oruko okunrin naa ni Abdul Rasheed Bello ti gbogbo eniyan mo si JJC, awon kan tun maa n pe ni Skillz.


Omo ilu Kano ni, leyin to pe odun merinla lo fi ilu Kano sile lo tedo siluu Oba Elisabeeti, London.

Ise orin nise re. Bakan naa lo tun ma n se agbateru awon olorin. A tile gbo wi pe o ti fi igba kan se agbateru fun D'banj ni akoko ti olorin naa fi wa niluu London ko to pada wale.

Ojo kerin osu kerin odun 1977 ni won bi JJC siluu Kano. Eyi tunmo si wi pe Jenifa ju u lo nitori odun 1976 ni won bi Sulia Ayetoro.

Musulumi ni Abdul Rasheed Bello. Bi o tile je wi pe a ko mo owo to fi mu esin re sugbon musulumi ni. Nipa ti Funke Akindele, inu esin Kristeni ni awon obi re bi si, esin yii lo si n se di akoko yii.

Abdul Rasheed Bello ti bi omo meta kan tele fun orisiirisii obirin meta saaju ko to pade Funke Akindele. Awon obirin meta yii kosi si pelu re mo.

Ni awon akoko kan seyin, D'banj se alaye Abdul Rasheed Bello (JJC) gege bi onimakaruru ati onireje eniyan. O ni eyi wa lara oun to mu awon pinya.

Bakan naa lo tun so wi pe, awon iwa owo re kan ko mo eleyii to mu awon olopaa ma wa kiri ilu London.

O ni isele igba naa fe se akoba fun oun, sugbon ori lo ko oun yo. O ni eyi si ni ohun to sokunfa orin ti oun ko ni akoko naa ti akole re je "mo bo lowo won".

Sugbon sa, Abdul Rasheed Bello pada so tenu re lori awon esun naa. O ni awawi lasan ni D'banj so lenu. O ni iranlowo ni oun se fun D'banj, aimoye owo lo si na oun lati ri wi pe D'banj naa di ilumooka. Koda, o ni aimoye ode orin oun ni oun ma n fun D'banj lanfaani lati korin. Sugbon nigba to ti je wi pe ahon atenu n ja, ija lo si de lorin dowe.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment