Smiley face

Sanyeri ra moto tuntun fun iyawo re

Ogbontarigi alawada onisima agbelewo, Olaniyi Afonja omo iya eleyin niluu Oyo, ti gbogbo eniyan mo si Sanyeri lagbo wi pe o ti ra oko tuntun aganran fun iyawo re, Hawawu Omolara Afonja bayii.


Gege bi awon olofofo wa se je ka mo bo se n lo, won ni gbogbo ilu Ibadan ni Hawawu ti pa laro bayii pelu moto re tuntun naa.

Ti e ko ba gbagbe, ojo kinni osu kejila odun 2013 ni Sanyeri so yigi Hawawu niluu Eko Oba Rilwan Akiolu omo Kutere leyin ti Hawawu ti bi omo meji fun un tele.

Awon omo meji naa ni Olasunkanmi ati Boluwatife.

Sugbon nigba to di odun 2014, esu gbiyanju lati kolu ebi naa lati pin won niya latari awuyewuye asemase kan ti won lo waye.

Sugbon leyin ohun gbogbo, alaafia pada joba laaarin awon mejeeji. Ife ati ayo won tun lo soke si i, eleyii to mu omo iya Niyi binu ra moto tuntun fun Iya Bolu to je aya re.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment