Smiley face

#SaveMayowa: Mayowa Ahmed ti kú o

Kehinde Oladeji 
Lóòtító̩, àìsàn ni a rí wò; kò sí e̩ni tó rí to̩ló̩jó̩ s̩e.

Mayowa Ahmed, e̩ni tí ó ti ń bá àìsàn je̩je̩re̩ jìjàkadì fún ìgbà pipé̩ tí jé̩ ìpè e̩lé̩dàá báyìí.

Tí a kò bá gbàgbé, o̩mo̩bìnrin yìí ni ò̩rò̩ rè̩ dá ó̩hùó̩hù sílè̩ láàrín àwo̩n òǹs̩èré tíátà àti àwo̩n gbajúmó̩ ènìyàn ilè̩ yìí lé̩nu ijo̩mé̩ta kan báyìí, nígbà ti àwo̩n e̩bí rè̩ ké gbàjarè pé ́wo̩n nílò owó fún ìtó̩jú rè̩ àmo̩ tí ìròyìn tún jáde wípé arúmo̩jé̩ ní ètò ìkówóje̩ náà.

Bí ó tilè jé̩ pé ò̩pò̩ awuyewuye ni ó bá ò̩rò̩ náà dé léyìí tí ó mú kí wó̩n gbé e̩sè̩ lé owó náà.

Lé̩yìn tí àwo̩n o̩ló̩pàá s̩e ìwádìí kíkún tí wó̩n sì fìdí òtító̩ múlè, wó̩n yò̩ǹdà owó náà fún àwo̩n e̩bí rè̩ wó̩n sì gbe lo̩ sí ìlú South Africa fún ìtó̩jú àisàn tí ó ń dà á láàmú náà.

Àmó̩ ni o̩sán o̩jo̩ àìkú, ní nǹkan bí agogo kan ni ò̩kan lára e̩bí rè̩, Asiwaju Foye, túfò̩ ikú Mayowa lórí è̩ro̩ Twitter.

"By Allah, in who's hands our lives is,

Mayowa Ahmed has left us in this world.

We pray that Jannat becomes her home.

#RIPMAYOWA.

Kí o̩ló̩run ó fò̩run ke̩.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment