Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K (30)

#ayeOlabisiK30

Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K (30)

Sii Olootu Yoruba Dun,



Mo tun fi asiko yii ki gbogbo eyin ololufe mi lori Yoruba Dun. Adanwo kekere ati eyi to tobi ko ni deba yin. Ti a ba wa ri eni to n la n isoro kan tabi ekeji koja, Olorun Oba alaanu yoo gbe won gori gboogbo isoro won patapata. Oba to ba okun soro ti okun gbo. Oba to ji oku ojo meta dide ninu isa oku. Olorun oba to n gbo adura yoo gbo adura gbogbo wa.



Awon Yoruba ni ti ina ko ba tan laso, eje ki i tan ni eekanna. Ibi a si roko si ti, ibe naa ni a n fabo si. Leyin igba ti oga mi fi tipatipa ba mi sun tan ni ile itura yii. 

Ore oko mi pada wa ba mi, awa mejeeji si kori si ile iwosan ni ale ojo naa. A paro fun won ni ile iwosan wi pe awon omo asunta kan niwon dena demi, ti won si fi tipatipa ba mi sun. Dokita fi wa lokan bale wi pe kosi iyonu, ati wi pe oun se itoju mi bo se to ati bo ti ye.




O fun mi ni ogun ti i dena oyun airotele. Bakan naa ni won fun mi beedi wi pe ki n sun si, nitori pe mi o le lo si ile mo. Dokita tun fi ye mi wi pe oun yoo se ayewo kokoro aisan koogbogun ti a mo si HIV fun mi.



Eleyii jami laya pupo nitori wi pe onisekuse eniyan ni oga mi, awon irin re ko si mo. Niwon igba ti o je wi pe eniyan o le ti bi oju mo eni ti o ba ni arun kogboogun, bi oga mi tile ni lara bawo gan-an ni mo se fe mo. A fi ki Olorun alaanu se anu re fun mi. Abi iru adanwo wo leyii? 


Ki n si ti mo ki n ti bo sile ninu ọkọ nigba ti awon oloriburuku okunrin ti won wa gbe mi so wi pe mo ni anfaani lati bọ sile ninu ọkọ awon ti ọkan mi o ba lọ mo.




Mo wa lori beedi nibi ti mo sun si ti mo n ka oke aja. Orisiirisii ero lo n wa si mi lokan. E gbona, ti o ba lo je wi pe mo ti ko arun yii lotito, se temi o ti ba je patapata bayii? Iya ko toya, afada pakun, ada sonu, ikun tun dohun airimo. 

Mo saa fi okan mi gba adura.  Igba yii ni mo se akiyesi wi pe ore oko mi o si pelu mi mo. Igba to ya die lo wole wa. Mi o mo ohun to n se nita to fi pe too bee. Mo beere boya ọkọ afesona mi ti pe e pada.



O si je ko ye mi wi pe o ti pe oun pada. Ko so ju bee lo fun mi. O le je oko afesona mii naa lo n ba soro to fi pe to bee nita. Tabi sugbon kan ko si nibe, gbogbo ohun to sele pata ni won ti bara won so lori foonu. Oro naa ba emi gan-an alara lokan je. 

Imi kekere leti awo gbegiri, ka nu kuro ka maa jeun lo. Bi o ba kuro loju. Ko le kuro lokan. Amo kini kan lo dami loju, bi a ba sare ki oju ma ti ni, ti oju ba ti ni, are ka maa ku ni kan loku. 





Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment